Susan Wojcicki
From Wikipedia, the free encyclopedia
Susan Diane Wojcicki (tí a bí ní oṣu keje ọjọ́ 5, ọdún 1968) jẹ́ olùdarí ìdókòwò ara ìlú Poland-Amẹrika tí ó jẹ́ alákòóso YouTube láti ọdún 2014. Àkójọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ jẹ́ $765 million ní ọdún 2022.[1]
Quick Facts Ọjọ́ìbí, Iṣẹ́ ...
Susan Wojcicki | |
---|---|
Wojcicki in September 2016 | |
Ọjọ́ìbí | 5 Oṣù Keje 1968 (1968-07-05) (ọmọ ọdún 55) Santa Clara County, Kalifọ́rníà, U.S. |
Iṣẹ́ | Business executive |
Title | CEO of YouTube |
Board member of | Salesforce Room to Read UCLA Anderson School of Management |
Olólùfẹ́ | Dennis Troper (m. 1998) |
Àwọn ọmọ | 5 |
Àwọn olùbátan | Esther Wojcicki (mother) Stanley Wojcicki (father) Anne Wojcicki (sister) Janina Wójcicka Hoskins (grandmother) Franciszek Wójcicki (grandfather) |
Signature | |
Close
Wojcicki ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ìmọọ-ẹ̀rọ fún ogún ọdún.[2][3] Ó kópa nínú ìṣẹ̀dá Google ní ọdún 1998 nígbà tí àwọn olùdásílẹ̀ rẹ̀ kọ́kọ́ ṣètò ọ́fíìsì wọn síbi gáréèjì ilè àwọn òbí rẹ, tórúkọ wọn ń jẹ́ Esther àti Stanley Wojcicki. Ó ṣiṣẹ́ bíi olùṣàkóso ìtajà àkọ́kọ́ ti Google ní ọdún 1999, lẹ́yin náà, ó jé olùdarí ìpolówó ọjà ní ilé-iṣẹ́ náà lórí ẹ̀rọ-ayélujára. Lẹ́yin tí ó ṣàkíyèsi àṣeyọrí ti YouTube, ó da lábàá pé kí Google rà á, wọ́n fọwọ́ sí àdéhùn náà fún $ 1.65 billion ní ọdún 2006. Wọ́n sì fi sípò alákòóso YouTube ní ọdún 2014.